Aṣiwaju ẹsin ijọ One Love Foundation niluu Ibadan, Sat Guru Maharaj-ji ti fi ọrọ lede wi pe iwọde ti awọn ọmọ Naijiria n gbero lati gunle bẹrẹ lati ọjọ kini oṣu kẹjọ ọdun yii kii ṣe fun anfani orilẹede yii rara.
Ninu atẹjade to fi sita nibi ipade awọn oniroyin to waye lọjọ Aje ninu ọgba ile ijọsin rẹ to n bẹ lopopona marosẹ Ibadan si Eko, Maharaj-ji ni awọn oloṣelu ti o ti ṣe akoso orilẹede yii tẹlẹri lo ṣe okunfa awọn ipenija to n waye lọwọlọwọ bayii, bẹẹ sini iwa ajẹbanu ti bẹrẹ lati ipasẹ awọn Oyinbo tofun orilẹede Naijiria ni ominira.
Aṣiwaju ẹsin naa ṣe alaye wi pe ohun ti o tọ ni ki awọn eeyan ilu ṣe iwọde lati fi ẹhonu han, ṣugbọn iwọde naa le di nnkan to mu ewu dani ti wọn ba ti ọwọ oṣelu bọ ọ.
O tẹsiwaju wi pe iwọde naa ko ni anfani kankan ti yoo ṣe fun ẹya Igbo, Yoruba ati gbogbo awọn ẹkun Guusu ilẹ adulawọ nitori akoba ti o le ṣe fun eto oṣelu ati ọrọ aje Najiria.
Maharaj-ji kede wi pe ko si agbara tabi omimi kan ti o le yọ arakunrin ati adari ohun, Aarẹ Bọla Tinubu nipo. O ni ohun ti Aarẹ nilo ni lati ṣe amulo agbara ifẹ ti o fi ṣe akoso ipinlẹ Eko ti gbogbo nnkan fi tuba, ti o si tuṣẹ fun gbogbo eeyan.
Gbogbo nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ lórí ètò ìwọ́de 'ebi ń pawá'
MTN ti gbogbo iléeṣẹ́ wọn pa káàkiri Nàìjíríà
Kò ṣẹ́ni tó lè ní ká má lo gbàgede Eagles Square l'Abuja fún ìfẹ̀hónúhàn – Alákòso ìwọ́de
Ọkan lara awọn alakoso fun eto iwọde ifẹhonuhan 'ebi n pa wa,' eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ti sọ pe ko sẹni to le da awọn duro lati lo gbagede Eagle Square to wa niluu Abuja.
Damilare Adenola to je alakoso eto fun ẹgbẹ Take It Back Movement lo sọ eyi lọjọ Aiku to kọja nibi ifọrọwerọ to ṣe nileeṣẹ amohunmaworan Channels TV.
Adenola sọ pe awọn ko ni adari tabi baba isalẹ kankan to n ṣagbatẹru ifẹhonuhan to fẹẹ waye, bi ko ṣe pe gbogbo ọdọ Naijiria ti ebi n pa ni wọn pawọpọ lati jade sita sọ ẹdun ọkan wọn.
Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ níbi ètò orin kíkọ, èèyàn mẹ́sàn-án jáde láyé
Wo ìkìlọ̀ tí ọmọbìnrin ààrẹ Nàìjíríà Folasade Tinubu-Ojo ṣe fáwọn ìyálọ́jà lórí ìwọ́de tó ń bọ̀
Lati bi ọsẹ meloo sẹyin ni ariwo naa ti n lọ kaakiri igboro pe awọn ọdọ fẹẹ korajọ lati ṣe iwọde ifẹhonuhan kaakiri ilẹ Naijiria, nibi ti wọn ti n beere fun ayipada ninu eto ati ilana iṣejọba.
Ifẹhonuhan ọhun lawọn eeyan ti n pariwo lori ikanni ayelujara kaakiri agbaye, ati pe gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria lawọn ọdọ ati araalu yoo ti pejọ.
Kii ṣe ahesọ wi pe owo ounjẹ ati gbogbo nnkan ti lọ soke, leyi to ṣoro fun araalu lati mu ọwọ lọ sẹnu, iyẹn latigba ti ijọba ti kede yiyọ owo iranwọ ori epo ti a mọ si ‘subsidy’.
Adenola sọ pe dukia ijọba to wa fun lilo araalu ni gbagede Eagle Square jẹ, to si ni minisita fọrọ eto FCT, Nyesom Wike ko ni nnkan meji to fẹẹ ṣe ju lati gba wọn laaye lọ.
Lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun ti a wa yii ni awọn ọdọ buwọ lu lẹta kan ti wọn fi ranṣẹ si minisita Wike, nibi ti wọn ti n beere fun anfaani lati lo gbagede Eagle Square fun eto ifẹhonuhan wọn.
Ṣugbọn ṣa, minisita fun FCT lọjọ Abamẹta to kọja sọ pe oun ko tii gba lẹta lati ọdọ ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan wi pe awọn fẹẹ lo Eagle Square.
Nigba to n sọrọ, Adenola sọ pe awọn eto ti wọn n ṣe lọwọ lo fa idaduro ti minisita ko ṣe tii ri lẹta ọhun gba, ṣugbọn to sọ pe lẹta naa yoo tẹ ẹ lọwọ loni, ọjọ Aje.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “O ṣee ṣe ki minisita mai tii gba lẹta naa nitori awọn kan to wa ninu ijọba ti wọn ko fẹ ko ṣee ṣe, tabi ko jẹ pe ki minisita naa ma ṣe otitọ nipa gbigba lẹta naa.
“Bi Wike ba sọ pe oun ko tii gba lẹta ọhun, ọna abuda ni lati gba a lori ayelujara nitori pe ileeṣẹ rẹ ti n gba nnkan lori ayelujara. Bo ba sọ pe oun ko tii gba, o ṣee ṣe ko rii gba ninu iwe iroyin. To ba si loun fẹẹ gba a, a maa fun un lọjọ Aje.”
Bakan naa nigba to n tẹsiwaju lori lilo Eagle Square, minisita sọ pe dukia ijọba ni gbagede naa, ati pe ẹtọ araalu ni lati lo o.
“Otitọ to wa nibẹ ni pe dukia ijọba ni Eagle Suare jẹ. Nigba ti mo ri fọnran minisita, iyalẹnu lo jẹ fun mi nitori pe niṣe lo sọ pe a gbọdọ san owo lilo, ka tun san owo aabo ati awọn nnkan miran.
“Ibeere mi si minisita ni wi pe: bawo ni minisita ṣe lero wi pe pẹlu iye ọdọ Naijiria ti wọn n gbe ninu iṣẹ ati oṣi, ti wọn ko niṣẹ lọwọ san owo bantabanta bẹẹ.
“A maa lo gbagede Eagle Square lọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2024.”
“Ọrọ abuku ni lati sọ pe awọn alakoso ifẹhonuhan yii ko foju han''
Siwaju sii ni Adenọla sọ pe ọrọ abuku nla ni lati sọ pe awọn alakoso eto ifẹhonuhan yii ko foju han sita, nitori pe gbogbo ẹni ti ebi n pa lo lọwọ ninu rẹ.
“Ọrọ abuku onigbameji ni lati sọ pe awọn alakoso ifẹhonuhan yii ko foju han, wọn ko da wọn mọ.
Awọn alakoso eto ifẹhonuhan yii ni awọn ọmọ Naijiria ti ebi n pa.
“Awọn to ṣe agbekalẹ iwọde naa lawọn ọmọ Naijiria ti ko ni ireti, ti wọn si n rin kaakiri lai ni afojusun.
Ati pe ọkan lara ohun to ṣokunfa eto ifẹhonuhan #EndBadGovernance yii ni ebi to n pa araalu gidi.